Mo lero pe gbogbo wa la ma pe isoro kan to n dojuko egbe agbaboolu Chelsea ni saa ti awa yi ni isoro atamatase ni owo iwaju ti o si je ohun ti o n ko gbogbo awon ololufe egbe abgabu naa lomi nu. Egbé agbàboolu yi ni ari pe isowo gba boolu won ti yato lati igba ti akonimagba tuntun ti oruko re je Sarri ti gba ise akonimagbe egbe agbaboolu na.

Ama isoro ti ebge agbaboolu na n dojuko lowo lowo bayi ni isoro atamatase ti muse muse re damuse, nitoripe awon atamatase meji ti won ni lowo bayi iyen Morata ati Giroud ni ikan o fi be senure fu ti oluko won si n woye lati lo gbe atamatase agbaboolu omo Juventus ti o n gbaboolu lowo pelu ayalo ninu ikò agbaboolu AC Milan.

Ninu iwoye temi, bi igba ti eniyan wa leti omi ti o si fi ito san owo lo je, ti omo eleran si n je eegu lori nitori wipe omo okunrin ti o gba boolu pelu ayalo ninu ikò Aston Villa ti a ma si Tammy Abraham n se gudugudu meje ati yayamefa lowo bayi.

Tammy Abraham ti apetan oruko re je Kevin Oghenetega Tamaraebi Bakumo-Abraham ni o n GBA boolu gege bi atamatase ti o si n se daradara ni ikò Aston Villa ti o ti n gbaboolu pelu ayalo. Ojo ori re kosi ti ju ogun odun olekan, odun 2004 ni o ti bere si n gba boolu fun ikò oje wewe Chelsea titi di odun 2016 nigba ti o pegede si ikò ti awon agbalagba ti o si ni anfani lati gba boolu ni igba meji pere fun ikò na.

Nigba ti saa 2016 pari ni won fi sowo sinu ikò Bristol City pelu ayalo, kete ti omo okurin yi ti dara po ma won ni o ti bere si ri àwòn e. Idije àkókó ni oti bere si gba boolu wo inu àwòn nigba tí o wolé fun Josh Brownhill lasiko ìgbà ti won koju Wigan Athletic ti o si gba boolu akoko si inu àwòn fun ikò Bristol City tí idije naa si pari si amin ayo meji si eyokan. Idije ekeji ti won ti koju ikò Wycombe Wanderers ni o ti bèrè ti o si tun gba amin ayo kan ti won fi gbeye lowo ikò Wycombe Wanderers wolé.

Ninu ifesewonse ti oje ogoji níye ti omo okunrin yi gba fun Bristol City ni oti ni aafani lati gba boolu ti ótó ogún o le meta níye wo inu àwòn. Tammy Abraham ni o tun darapo ma ikò Swansea City ti o si mi àwòn fun won ni igba mejo ninu igije ogbòn o le mesan.

Tammy Abraham ni ikò Chelsea tun fi sowó sinu ikò Aston Villa nibi ti o ti n gba lowo bayi lati odun 2018 ti osi ti gba idije ti o to ogún níye pelu ami ayo merindinlogun fun won. Tammy Abraham ti gba boolu ti o to ogorun odin mefa fun gbogbo ikò ti o ni aafani lati gba boolu pelu ayalo ti o si ti gba àmìn ayo ogoji ólé merin won inu àwòn.

Pelu big ikò Chelsea se n gba boolu lasiko ti awan yin, atamatase ti ojo ori re si kere ti osi ti ni opolopo iriri bi Tammy Abraham ni won nilo ti ko si ni na won ni owo tulutulu. Mi o ri Higuain bi eniti o le yan ju isoro ti o n dojuko ikò Chelsea lówó seni o dabi ìgbà ti won fe lo ko owo sofo danu ni o ri.

Ari wipe ikò Chelsea ma n ni awon òjè wéwé ti o dara sugbon ti won ko n fun won laaye lati gba boolu fun won. Ninu won lati ri Sinclair, piazon ati bebelo.

Mo lero wipe e gbadun àyokà yi, otun di igba Miran, emi ni omo yin, aburo yin, ore yin @oxygen02. E se fun kíkà👍